Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá l’ó sọ bẹ́ẹ̀.

Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kan l’ó sọ wípé, Àpapọ̀ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, sọ fún ẹ, ìwọ Lucky Orímisàn Ayédatiwa, tí o pe ara rẹ ní gómìnà ìpínlẹ̀ Ondó; oò kìí ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Ondó o!

Ìwọ l’o pe’ra ẹ bẹ́ẹ̀! Lucky Orímisàn Ayédatiwa, kúrò l’orí àlééfà ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ó ti wá d’ojú ẹ̀, báyi o! O nṣẹ̀ sí òfin àti agbára ìṣè’jọba-ara-ẹni ti Orílẹ̀-Èdè Olómínira Tiwantiwa ti Yorùbá; bẹ́ẹ̀ náà ni o nṣẹ̀ sí òfin àgbáyé!

Ibi t’o jóko sí yẹn, ní Àkúrẹ́, ti kúrò nínú Nàìjíríà; ó ti di Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá; orílẹ̀-èdè tí ó yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí ìwọ f’ara mọ́; o f’ara mọ́ Nàìjíríà; kò burú; máa bá nàìjíríà ẹ lọ; kúrò l’orí àlééfà ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá! À b’oò l’etí ni? Yorùbá kò sí l’ara nàìjíríà mọ́!

  Ayédatiwa, Kúrò L'orí Àlééfà Ọmọ Yorùbá

 

Ọ̀gá ẹ, t’ó ṣáájú ẹ, Rotìmí Akérédolú, ti gba lẹ́tà l’ati oṣù kéjìlá ọdún 2022, ìwọ náà dẹ̀ wà ní’bẹ̀ nígbànáà; ẹ jìjọ gba lẹ́tà náà ni; nítorí ìwọ ni igbá kéjì ẹ nígbàyẹn; ẹ jìjọ wà l’órí àlééfà ni, nít’orí “joint ticket” l’ẹ lò, l’abẹ́ òfin Nàìjíríà, l’ati jọ dé bẹ̀; nít’orí náà, o mọ ohun tí a nsọ! O ò lè sọ wípé oò mọ̀ọ̀!

Ní ọjọ́ kọ́kàn-dín-l’ọgbọ̀n,  oṣù kéjìlá, ọdún 2022, ni ẹ ti gba ìwé, tí ọmọ Yorùbá, l’abẹ́ àsíá ÒMÌNIRA YORÙBÁ 2022, kọ sí yín, wípé, a dúró l’orí Ìkéde Òmìnira tí a ti ṣe l’ati ogúnjọ́, oṣù kọ́kànlá, ọdún 2022, wípé  ilẹ̀ Yorùbá, àti ọmọ Yorùbá ti já’de kúrò nínú nàìjíríà; a kìí ṣe ara nàìjíríà mọ́!

Ká Ìròyìn: Àgbà’yà, Bísí Àkàndé Gba Ipò Pro-Chancelor (Al’aga Ìgbìmọ̀) Fásítì Ìbàdàn

Ẹ kúrò l’orí ilẹ̀ wa! A ò sọ wípé ìwọ Lucky Orímisàn Ayédatiwa; a ò sọ wípé oò kìí ṣe ọmọ Yorùbá o! A mọ̀ ẹ́ sí ọmọ Yorùbá; a mọ̀ ẹ́ sí ọmọ ìpínlẹ̀ Ondó; ṣùgbọ́n, ìpínlẹ̀ Ondó ti wá yàtọ̀, nísiìyí, sí ìpínlẹ̀ Ondó tí ó wà tẹ́’lẹ̀! O mọ òfin!

 

Ayédatiwa, Kúrò L'orí Àlééfà Ọmọ Yorùbá

 

Ìpínlẹ̀ Ondó tí ó wà, tẹ́’lẹ̀, nígbàtí ìwọ àti Akérédolú wà l’orí àlééfà, kí ó tó di ogún’jọ́ oṣù kọ́kànlá, ọdún 2022, jẹ́ ìpínlẹ̀ Ondó nínú Nàìjíríà; l’abẹ́ Nàìjíríà ni ìwọ àti Akérédolú fi wọ orí àlééfà ìpínlẹ̀ Ondó; ṣùgbọ́n l’ati ogún’jọ́ oṣù kọ́kànlá ọdún 2022, ìpínlẹ̀ Ondó kò sí l’abẹ́ nàìjíríà mọ́!

Àgàgà, l’ati ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin ọdún 2024 yí, a ti ṣe ìbúra-wọ’lé fún olórí ìjọba orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba – D.R.Y), l’ẹhìn tí a ti ṣe Ìpolongo Ìṣè’jọba-Ara-Ẹni (Sovereignty) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ní ọjọ́ náà, bákannáà; èyí tú’mọ̀ sí wípé, l’ati ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin, ọdún yí (2024), ìwọ Lucky Orímisàn Ayédatiwa, a nsọ fún ẹ wípé, Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y, ti wà l’orí àlééfà, ṣùgbọ́n ìwọ Lucky Orímisàn Ayédatiwa, óò fẹ́ kúrò l’orí ìjóko-àga àlééfà náà ní ìpínlẹ̀ Ondó.

O lè máa béèrè wípé tani gómìnà ìpínlẹ̀ Ondó l’abẹ́  Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá. Ìwọ má ṣe wàhálà l’orí ìyẹn.

Tì ẹ ni wípé, kúrò l’orí alééfà ọmọ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Ondó, tí o kò bá fẹ́ kan ìdin nínú iyọ̀. A ti sọ, sọ, sọ tó; Lucky Orímisàn Ayédatiwa, JÁ’DE KÚRÒ NÍ Ọ́FÍÌSÌ ÌJỌBA NÍ ALÁGBÀKÁ NÍ ÀKÚRẸ́! – TINUBÚ NKÓ Ẹ ṢI’NÀ NI! YORÚBÁ TI DÁDÚRÓ, PÁTÁPÁTÁ, L’ATI ỌJỌ́ KÉJÌLÁ OṢÙ KẸ́RIN, ỌDÚN YÍ!

A nk’ìlọ̀ fún ẹ ni o! Ó ku díẹ̀ t’o máa tẹ́! Àfi k’o tètè já’de kúrò ní Alágbàká; Yorùbá kò sí l’abẹ́ Nàìjíríà mọ́!