Ìròhìn tí a gbọ́ sọ pé, tí ó bá di ọdún tí ó nbọ̀ yí, ìdajì àwọn ọmọ tuntun ní yíò jẹ́ dìdìnrìn tàbí apọ̀dà! – èyí kìí ṣe ìpín ti wa ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá o! ṣùgbọ́n a ní láti mọ kí ló nlọ, kí a le ṣọ́ra gidi! Àfi kí á ríi dájú, nígbà gbogbo, pé ojú-méjèèjì ni a fi ntẹ̀lé Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé kalẹ̀ fún Ìgbésí-Ayé Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, Ìran Yorùbá, àti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, títí ayé, láti ọwọ́ Ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí ojú wa kí ó rí’bi o!
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Ṣé a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí, ẹni ibi gbáà ni wọ́n; bí wọ́n ti nlo abẹrẹ́ àjẹsára láti pa ọmọ ènìyàn, náà ni wọ́n nlo ayédèrú irúgbìn; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n nda oríṣiríṣi àrùn sínú ayé.
Èyí tí a tún gbọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára ní àìpẹ́ yí ni pé, lára àwọn òògùn tí wọ́n nṣe láti fi ṣe ìwòsàn fún ẹni tí ó ní kòkòrò búburú nínú ara, lára àwọn òògùn náà fún’ra wọn ni ó máa nfà ìrẹ̀wẹ̀sì fún iṣẹ́-ṣíṣé tí ó yẹ kí àwọn kòkòrò tí ó jẹ́ rere nínú ara ó ṣe – àsẹ̀yìn wá, àsẹ̀yìnbọ̀, ó máa nfa àrùn kí ọmọ tí wọ́n bí ó ya dìndìnrìn tàbí apọ̀dà!
Ohun tí ó ṣe pàtàkì fún àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ti Democratic Republic of the Yoruba, ni kí á ri pé a ò yà s’ọtún tàbí yà s’osì kúrò ní Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé lé Màmá wa Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá lọ́wọ́, fún Ìran Yorùbá; nípa èyí ni a ò fi níí gba ìgbàkugbà kankan, yálà ní onjẹ tí a njẹ tàbí òògùn tí a nlò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÀMERICA TI F’ỌWỌ́ SÍ ỌSIN ADÌẸ LÁTI YÀRÁ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀
- ẸGBẸ̀RÚN MÁRUN NÁÍRÀ NI ÀWỌN ARÁ ÌLÚ NÀÌJÍRÍÀ FI DA’LẸ̀ ARA WỌN !
- ÀNFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
- ÒFÉGÈ ÌRÀNLỌ́WỌ́: ọmọ Yorùbá, máṣe yà sí’bẹ̀ !
- ỌMỌKÙNRIN KAN ṢE’KÚ PA BÀBÁ TÓ BÍ BÀBÁ RẸ̀ NÍTORÍ OKO
- JAMIU ABÍỌ́LÁ NHU ÌWÀ ỌMỌ ALÈ
- ṢÍṢE ARA LÓGE NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ