Iyán l’oúnjẹ, ọkà l’oògùn, àìrí rárá l’àńjẹ̀kọ, k’ẹ́numádilẹ̀ ni ti gúgúrú. Èyí ń tọ́ka sí bí àwa ìran Yorùbá ti ṣe ní oríṣiríṣi oúnjẹ, kìíwá ṣe oúnjẹ lásán, ṣùgbọ́n àwọn oúnjẹ tí ó ń ṣe àǹfààní ní àgọ́ ara wa.

Kìí se àwọn ayédèrú, tàbí èyí tí a gbìn ní ọ̀nà ti ìgbàlódé pẹ̀lú oríṣiríṣi oògùn tí ó leè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara wa.

Ẹ wo àwọn babańlá wa láyé ọjọ́un, gbogbo wọn ni wọ́n ń dàgbà tí wọ́n sì ń dògbó látàrí oúnjẹ afáralókun tí wọ́n ń jẹ pẹ̀lú oríṣiríṣi ewébẹ̀ bí àpẹẹrẹ: Ẹ̀fọ́ òdú, ẹ̀fọ́ ṣọkọ, ẹ̀fọ́ wọ̀rọ̀wọ̀, ẹ̀fọ́ gbúre, ẹ̀fọ́ ebòlò, ẹ̀fọ́ ìgbàgbá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

Bẹ́ẹ̀ náà ni a tún ní àwọn èso lorísìírísìí, bíi  ọ̀sán, kajú, àgbálùmọ̀,àrín, ìgbá, ìbẹ́pẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Bákan náà ni a tún ní àwọn èròjà ìsebẹ̀ tí kò lóǹkà, díẹ̀ lára wọn ni, irú, ògìrì, ataare, ata ilẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Ǹjẹ́ mélòó nínú àwọn ewébẹ̀ àti èso tí a dárúkọ wọ̀nyí, ni ó wà nínú àwọn ọjà wa ní ilẹ̀ Yorùbá lónìí? Tí a ó bá sì rí díẹ̀ nínú wọn ó le jẹ́ wípé láti ilẹ̀ òkèèrè tàbí òkè Ọya ni wọn ti kó wọn wá,bẹ́ẹ̀ ni ẹ óò máa gbọ́, iṣu Àbújá,rodo Kánò, apple Kútọnu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Gẹ́gẹ́ bí màmá wá ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa pé, ní ọ̀nà ti ayé àtijọ́ ni àwọn ilé ìtajà oúnjẹ wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ìpèsè oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, a ó máa gún iyán nínú odó ni gẹ́gẹ́ bí àwọn màmá wa ti máa ń ṣeé láyé àtijọ́, àwa kò nílò ẹ̀rọ ìgbàlódé láti fi gún ìyàn rárá.

Nítorí náà, ẹ̀yin àgbẹ̀ wa, iṣẹ́ pọ̀ fún wa gidigidi láti ṣe,ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ sí ní ronú ọ̀nà tí a leè gbà ṣeé láti ríi dájú pé a dá gbogbo àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti di ohun ìgbàgbé ní ilẹ̀ Yorùbá padà,nítorí pé ọkàn lára àṣà wa náà ni oúnjẹ jíjẹ wà, tí a sì ní láti gbé lárugẹ, bí a ṣe ní oríṣiríṣi oúnjẹ bẹ́ẹ̀ náà ni a ní oríṣiríṣi ọ̀nà tí a fi ń pèsè wọ́n tí a sì fi ń jẹ wọ́n,à ti wípé, ọwọ́ wa ni a ó máa fi jẹ àwọn oúnjẹ òkèlè tí a kò sì ní lo síbí tàbí àmúga láti fi jẹun.

kí a má sì ṣe lo ohunkóhun tí ó leè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara wa láti gbìn ohunkóhun, ilẹ̀ ọlọ́ràá ni Olódùmarè fi fún wa,kò sí ohun tí a gbìn sínú rẹ̀ tí kò ní hù jáde láìlo oògùn ti ìgbàlódé.