Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fi hàn pé, ẹ̀tẹ́ àwọn ọmọ Íbò lórí ilẹ̀ Yorùbá, kù sí dẹ̀dẹ̀. A kúkú ti mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀ sí alágídí; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa nsọ̀rọ̀ láì fi làákàyè si: ṣé wọ́n rò pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá jẹ́ Nigeria ni?

Dájú-dájú, ọ̀rọ̀ ti kàn wọ́n lára pé Yorùbá ti dá dúró, àti pé gbogbo ìgbéraga wọn ní ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n nfọwọ́ lalẹ̀ fún ọmọ Yorùbá, lórí ilẹ̀ Yorùbá, pé ó máa lẹ́hìn!

Àì fi làákàyè gbé ọ̀rọ̀ náà ti wá njẹ́ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ ní ìgboro ẹnu! Ṣùgbọ́n, ohun tí ó bá wu ẹlẹ́nu ni ó lè fi ẹnu ẹ̀ sọ o! Ohun tí kò bá dẹ̀ wu onílẹ̀ ló lè sọ pé òun ò fẹ́ lórí ilẹ̀ òun; àì tẹ̀lé òfin onílẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀, àjèjì ti ṣe tán àti tẹ́ pátápátá nìyẹ̀n.

Nínú ìgbéraga àwọn ọmọ Íbò wọ̀nyí, a gbọ́ pé wọ́n ní kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le “pín” Nigeria. Àì mọ’nú rò wọn ni ó jẹ́ kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wèrè yí! Ṣé àwọn ni amúnisìn tó kó nigeria papọ̀ ni, tí wọ́n fi nsọ pé kò sí ẹni tí ó lè “pín” Nigeria.

Kẹ́kẹ́ máa tó pa mọ́ wọn lẹ́nu, nígbàtí Nàìjíríà fún’ra rẹ̀ bá sá’ré kàbàkàbà kúrò lórí ilẹ̀ Yorùbá – ní àìpẹ́. Ṣé àwọn ọmọ Íbò yí kìí tiẹ̀ máa nro’nú ni: wọ́n rò pé bí wọ́n ṣe nṣe lórí ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n á ṣe máa ṣe lọ. Ìgbà tí Nigeria yín fún’ra ẹ̀ bá sá’re kúrò lórí ilẹ̀ Yorùbá, ní àìpẹ́ yí, ló máa yé yín bí ẹnikan lè pín nigeria yín ọ̀ún tàbi kò s’ẹni tó lè pin.

Ẹ jọ̀wọ́, ẹni bá mojú àwọn ọmọ Íbò ní ilẹ̀ Yorùbá, kí ó bá wa ṣàlàyé fún wọn pé Nigeria ti pòórá láti ẹgbàá ọdún ó-lé-mẹ́rìnlá; kí ẹ tún bá wa sọ fún wọn pé ìpọ̀nrípọngbá wọn yẹ kó mọ̀ pé Yorùbá ti wà kí wèrè òyínbó kankan ó tó wá máa pe ibi kan ní “nigeria.”

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, World
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tún bà wa sọ fún wọn pé aà kìí ṣe “Western Region” gẹ́gẹ́bí a ṣe gbọ́ pé wọ́n nsọ; àwa ò mọ nkan tí ó mú gbólóhùn “Western Region” yẹn wá sí wọn lórí, tí kìí bá nṣe àìní’rò’nú!

Ṣé wọ́n gbàgbé ni pé ìkan nínú wọn – Aguiyi Ironsi – ló fagi lé “Region” láyé ijọ́un l’ọhún ni? Àbí wọ́n ti gbàgbé Ìtan ni? Níbo ni wọ́n ti wá rí “Western Region” èyí tí wọ́n nsọ o?!

Ẹ jọ̀ọ́, ẹ̀yin tí ẹ bá mojú wọn, ẹ bá wa ṣí wọn ní làákàyè, kí wọ́n le mọ̀ pé, ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjì-lé-lógún, ni ilẹ̀ Yorùbá ti kúrò lára Nàìjíríà o!

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣì nsọ̀rọ̀ “Region” lẹ́hìn tí Ironsi wọn ti fagi lé “Region”, ẹni yẹn nsùn; kò sì sí ní ayé nbí!

Ẹ bá wa fi sí ọpọlọ wọn pé, ọ̀rọ̀ agidí kọ́ ni eléyi, ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ni, ọ̀rọ̀ òfin dẹ̀ ni! Lẹ́hìn tí a ti ṣe ìkéde òmìnira wa, a tún ti wá ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni wa, ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí – ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, tí a dẹ̀ ti ṣe ìbúra-wọlé fún olórí Ìjọba wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́.

A mọ̀ pé àwọn ọmọ Íbò ní àṣà kí wọ́n máa rò pé gìrìgìrì ni kí àwọn máa fi ṣe nkan; ẹ bá wa sọ fún wọn pé ọ̀rọ̀ gìrìgìrì kọ́ ni eléyi: ọ̀rọ̀ Orílẹ̀-Èdè ni! Ẹ fi yé wọn pé áò kìí ṣe “Western Region,” Democratic Republic of the Yoruba ni wá – orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni tí ó tuntun jùlọ ní àgbáyé, a dẹ̀ ní ètò Òfin ti wa! Gbogbo gìrìgìrì wọn yẹn ó máa tẹ́ríba fún Òfin D.R.Y ni, wọn ò rí nkan ṣe si!

A gbọ́ pé wọ́n ní kò sẹ́ni tó le lé àwọn kúrò ní “Western Region;” ẹ bá wa sọ fún wọn pé Western Region nìyẹn; aò kìí ṣe Western Region; gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ, D.R.Y ni wá, orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ sí Nàìjíríà pátápátá; nítórí náà, ọ̀rọ̀ Western Region kọ́ ni eléyi.

Ẹni tó bá fẹ́ gbé ní orí-ilẹ̀ D.R.Y, gbọ́dọ̀ gbé níbẹ̀ GẸ́GẸ́ BÍ òfin D.R.Y bá ṣe sọ ni!

Tí wọ́n bá fẹ́ mọ̀ bóyá lóotọ́ ni Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dá dúró, kí wọ́n lọ sí àjọ àgbáyé láti lọ béèrè: ṣe bí wọn máa nrò pé kò sí bí àwọn ò ṣe jẹ́ ni? ẹhẹn-ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n le lẹ́ni tó máa bá wọn béèrè níbẹ̀; àti pé, àpọ́nlé la nfi gbogbo èyí tí a nsọ yí ṣe o, tí ẹ bá ta féle-fèle, ẹ máa kan ìdin nínú iyọ̀! Ẹ̀yin àti tani?

Wọ́n ní wọ́n sọ pé àwọn ti fowó ṣe òwò púpọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá! Ẹ jọ̀ọ́, ta ló bérè ẹjọ́ lọ́wọ́ yín?

Tí ẹ̀yin bá ṣe rere, ara kò ha ní yá yín bí? Ó ti wá njó yín lọ́wọ́ báyi, ẹ wá nsọ mọ́nọmọ̀nọ!