Ìwà tí àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà lórí ilẹ̀ Yorùbá ń hù sí ará ìlú kò yí padà o. Lẹ́yìn ohun tí ojú wọn rí ní àkókò #End Sars#, wọ́n ti gbàgbé wípé ìlú tí kò sí òfin ni ẹ̀sẹ̀ kò sí. A rí àwòrán ibi tí àwọn Ọlọpa bí mẹ́fà ṣe sùrù bo ọkùnrin kan ní òpópónà Jogunósinmi, ní agbègbè Alausa, ní ìlú Ikeja, láti fi tipátipá gba ẹ̀rọ alágbèká rẹ̀ lọ́wọ́ arákùnrin náà; bẹ́ẹ̀ ni ó sì ń pariwo pé òun máa pe agb’ẹjọ́rò òun pẹ̀lú bẹ́ẹ̀ náà ni wọn sì ń lù ú pẹ̀lú kùnmọ̀ láì kì íṣe màlúù.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Àwọn Ọlọ́pa Nàìjíríà Lórí Ilẹ̀ Yorùbá Kò Fi Ìwà Ipá Wọn Sílẹ̀ O

Irú ìwà ipá lórí ohun olohun báyìí kò lè bá wa gbé orí ilẹ̀ D. R. Y. Kí ẹ yára tètè gbọ́ o, ẹyin Ọlọpa aláṣọ dúdú, nítorí òfin máa wà fún gbogbo ènìyàn láti tẹ̀lé láì sí ìrẹ́jẹ.

Àwọn Ọlọ́pa Nàìjíríà Lórí Ilẹ̀ Yorùbá Kò Fi Ìwà Ipá Wọn Sílẹ̀ O