Àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Ẹgbẹ́ Àgbà Yorùbá láwọn kò faramọ́ èròngbà láti yọ  orílẹ-èdè Yorùbá kúrò lára Naijiria, pé ohun tí àwọn fẹ́ ni ìṣèjọba àpapọ̀ tòótọ́. Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

O yẹ kí àwọn ẹgbẹ́ àgbàyà yí mọ̀ pé kò sí ẹnití nfí ipá mú wọn láti darapọ̀ mọ́ orílẹ-èdè Democratic Republic of the Yorùbá tí o ti duro, àwa náà kó fẹ́ kó ẹran mọ́ èrò rárá. Oníkálukú ló ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin àgbáyé láti jẹ́  ọmọ orílẹ-èdè tí ó wùń. Àwọn ẹgbẹ́ yìí tẹnumọ fífaramọ́ ìṣọkan Naijiria, pé agbára wà nínú onírúurú ìgbé ayé àti àṣà pẹlú àjogúnbá wọn 

Ohun tí àwọn àgbà òṣì yí ńjà fún ni ìwà olè àti ìtẹríẹniba tí ó jẹ́ àjogúnbá wọn nínú Nàìjíríà. Àwọn ìkà kẹ́nimánìí tí wọ́n fẹ́ tẹ̀síwájú láti máa fi ìyà jẹ àwọn mẹ̀kúnnù, tí wọ́n sì ńta ìran wọn fún àjèjì láti parun nitori ìgbadun àwọn àti ọmọ wọn nìkan.

Àwọn Kan Tí Wọ́n Pe Ara Wọn Ni Ẹgbẹ́ Àgbà Yorùbá Kọ Orílẹ̀-Èdè Yorùbá Wọ́n Gbè Lẹ́hìn Àpapọ̀ Naijiria.

Àwọn Àgbà Ọ̀pọ̀nú

Àwọn egbé yìí ń pè fún àtúntò Nàìjíríà tí yíò fí àyè gba Ìpìnlẹ̀ kọ̀kan láti máa ṣiṣẹ́ nínú Nàìjíríà kan bíi ètò tí Améríkà, tí ijọba àpapọ̀ kì yíò lágbára tó bẹ́ẹ̀ lórí rẹ̀.

Ẹ jẹ́ ká béèrè lọ́wọ́ àwọn òpònú àgbàyà wọ̀nyí pé láti ó dín díẹ̀ lọ́gọ́ta ọdún tí wọ́n ti ńpariwo ẹnu fún àtúntò, kíni wọn mú bọ̀?

Àti pé ṣé ojú wọn fọ́ àbí etí wọn di pé Ọlọrun ti lo màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla láti gbà orílẹ-èdè tiwa, Democratic Republic of the Yorùbá fun wa, pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí tí ó dájú ni?

Yorùbá tí kúrò lára Naijiria lati ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wáọdúnóléméjìlélógún, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rìnlélógún, orílẹ-èdè wa yàtọ sí pátápátá, gbogbo ayé ló mọ̀ pé orílẹ-èdè Yorùbá kìí ṣe ara Naijiria mọ rara, nítorí náà àtúntò kankan ko kan wá rárá.

Ẹgbẹ́ yìí ń jà láti padà sí ìjọba àdaṣe agbègbè ara ẹni tí àwọn baba wọn tí ó dà Naijiria sílẹ̀ ń lo, èyí ti ìpínlẹ̀ kọ̀kan yíò máa dá’wó si àpò ìjọba àpapọ̀ láì sọ òmìnira wọn nù.

Àwọn Kan Tí Wọ́n Pe Ara Wọn Ni Ẹgbẹ́ Àgbà Yorùbá Kọ Orílẹ̀-Èdè Yorùbá Wọ́n Gbè Lẹ́hìn Àpapọ̀ Naijiria.

Gbogbo àgbáyé ló mọ̀ pè Naijiria kìí ṣe orílẹ-èdè lábẹ́ òfin àgbáyé nítorípé àkójọpọ̀ irọ́ àti ẹ̀tànjẹ náà ti parí láti ẹgbẹwaọdúnólémẹ́rìlá àti pé lábẹ́ òfin àgbáyé Democratic Republic of the Yorùbá jẹ́ orílẹ-èdè tí o tí duro tí ó sì tí fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ pẹlú ìjọba tí ara rẹ̀, ó sì bá òfin mú ní gbogbo ọ̀nà.

Ẹ́tọ́ wa ní lábẹ́ òfin Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé àti lábẹ́ ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ láti dá dúrò tí a bá fẹ́, a kò nílò ìfọwọ́sí tàbí àtìlẹ́hìn ẹnìkankan tàbí àwọn àgbà tí kò ní ọjọ́ ọ̀la rere yìí.

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Ẹnití kò bá tẹ́ l’ọ́run kó gba Naijiria lọ, iye àwa tí ó bá kú ní orílẹ-èdè D. R. Y náà ní IYP, kí àwọn àgbà ìka yìí àti àwọn tí ó rán wọn níṣẹ́ ibi dákẹ́jẹ́jẹ́ tàbí kí wọ́n gba irú ìdájọ́ Baṣọ̀run Gaa.