Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé.

Àwọn bàbá wa á máa sọ wípé “Ìfura l’òògùn àgbà, páńsá ò fura páásá já síná, àjà ò fura, àjá jìn, onílé tí ò bá fura, olè ni ó ko lọ”.

Òwe Yorùbá

Gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yoruba, ẹ jẹ́ kí a máa fura o. Gbogbo àwa ọmọ Yorùbá mọ̀ wípé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ àwọn baba ńlá wa, ewéko, eran ọ̀sìn, adìẹ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

 

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

 

Bill gate and co planning to replace animals meat with laboratory produced meat. Yoruba be warned!

Bill Gate so wípé kí wọ́n máa dẹ́kun màlúù ní dídà àti wípé màlúù tí ó ń jẹ ewéko ń ṣe àyípadà bá ojú ọjọ́, tí kì dẹ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Ka Ìròyìn: Bill Gates – Ìránṣẹ́ Apànìyàn Tí Àṣìtáánì Nlo Lati Ṣe’Jàǹbá Fun Aláwọ̀dúdú

O sọ wípé àwọn tii ń ṣe ìwádǐ àti wípé àwọn ní àjẹsára ọ̀fẹ́ láti máa gbé màlúù jáde láti inú ilé iyàrá ìwádǐ wọn.

Èròńgbà wọn ni láti ṣe ìrọ́pò ẹran tí ó dára tí ó ń jẹ ewéko tí ó ń ṣe ara àwọn ẹran náà àti ènìyàn ní àǹfànní, pẹ̀lú àwọn ẹran màlúù tí wọ́n ń dàgbà nínú ìyàrá ìṣèwádǐ ti wọn.

Ẹ jẹ́ kí a máa fura, kí á sì má gba eléyìí láàyè rárá nítorí àwọn oríṣiríṣi kẹ́míkà tí wọ́n ń pòpọ̀ nínú ìyàrá ìwádǐ wọn tí wọ́n ń fún àwọn ẹran màlúù náà, tí ó sì  jẹ́ ìpalára fún àwọn ẹran náà àti èèyàn pẹ̀lú.

Ẹ jẹ́ kí àwa ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá máa jẹ oúnjẹ, ẹja, ẹran-ọ̀sìn, àti ohun ọ̀gbìn gbogbo tí ó ń ṣe ara ní àǹfànní àti pàápàá oun tí ó máa ṣe ara eni ní pípé pẹ̀lú óúńje àdáyébá láì sí àbùlà kẹ́míkà kankan.

Èyí ni l’ara ètò rere tí ó wà nílẹ̀ fún gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.

Ka Ìròyìn: Ààrẹ Senegal Mú Owó Ìrìnnà Kúrò Ní Àwọn Onjẹ Tí Ó Nwọlé Sí Ìlú Rẹ̀

 

Bill gate and co planning to replace animals meat with laboratory produced meat. Yoruba be warned!