A rí ìròyìn kan lórí ayélujára níbití àwọn Fúlàní ti kọ’jú ìjà sí àwọn àmọ̀tékùn ìlú Nàìjíríà ní agbègbè kan tí à ń pè ní Igboba Community ni Sango, Àkúrẹ́.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

A gbọ́ pé níbití àwọn àmọ̀tẹ́kùn yí ti ń gbìyànjú láti lé àwọn màlúù tí wọ́n pè wọn sí láti bá ẹni tí ó ni oko lé àwọn Fúlàní àti àwọn màálù wọn tí ó lé ní ọgọ́fà kúrò nínú oko àgbẹ̀ náà.

Àwọn Fúlàní Darandaran Àti Àwọn Àmọ̀tẹ́kùn Gbéná W'ojú Ara Wọn O

 

Sùgbọ́n bí wọ́n ṣe ń padà lọ ni àwọn Fúlàní bẹ̀rẹ̀ sì ju òkúta, igi, ìgò lu àwọn àmọ̀tẹ́kùn tí rògbòdìyàn sì bẹ́ sílẹ̀ tí àwọn Fúlàní bẹ̀rẹ̀ si ní máa sá àwọn àmọ̀tẹ́kùn ní àdá bí ẹni sá egungun ẹran, ìjà náà di bí ìwọ kò bá lọ, yà fún mi, ó wá dí lílọ bíbọ̀ àwọn ọkọ̀ ojú opópó Àkúrẹ-Ado Express lọ́wọ́, oníkáluku bẹ̀rẹ̀ sí ní sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn. 

Ara àwọn ìwà ìjẹ gàba lórí ohun olóhun nìyí o. Síbẹ̀, òfin kí ẹnikẹ́ni má ṣe da ẹran jẹ̀ ní gbangba tí olóògbé Akérédolú, gómìnà ìgbà náà ní Ondo ti fi òfin náà lé’lẹ̀ láti ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹjọ ẹgbàá ọdún ó-lé-mọ́kànlélógún tí àwọn Fúlàní yìí sì ń ṣe àìgbọràn.

Àwọn Fúlàní Darandaran Àti Àwọn Àmọ̀tẹ́kùn Gbéná W'ojú Ara Wọn O

Ìwà àìbìkítà àti àìbọ̀wọ fún òfin ìlú tí àwọn Fúlàní ti ń hù láti ìgbà náà ni wọn kò yípadà yìí, ìwà ta ló máa mú mi lórí ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn.

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Ó sì kúkú dára bẹ́ẹ̀ fún àwọn àmọtẹkùn náà, ṣebí ará ilé wọn kìí yá wọn lára, ọmọ ìyá wọn ní wọ́n le mú f’ogun, àwọn ni wọ́n ṣáà ń mú àwọn ọmọ ológun IYP lórí ilẹ̀ bàbá wọn, D. R. Y. fún MAKINDE ní Ìbàdàn làìpẹ́ yìí, kíló wá ṣe wọ́n báyìí o ti wọn kò lè mú àwọn Fúlàní?, ilé ìwòsàn tí gbà wón lálejò bayi nibitì wọ́n ti ń gba ìtọ́jú.