Ìròyìn kan jáde pé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Ìbàdàn ti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn míràn, látàrí àfikún owó ile ìwè wọn.

Ilé ẹ̀kọ́ Fásitì yí wà ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá(Democratic Republic of the Yorùbá, DRY) ti ìlú agbèsùnmọ̀mí Naijiria ń fi ipá jẹgàba lórí rẹ̀, ìjẹgàba àwọn agbésùnmọ̀mí náà ló fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí eléyìí, ṣùgbọ́n láìpẹ́ yí tí àwọn Adelé wa bá ti bọ́ sí ipò wọn káàkiri olú ilé iṣẹ̀ ìjọba ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá DRY), àlàkalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ tó yè kooro ti wà nílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ni kò ní sí ìfẹ̀hónúhàn kankan nítorí pé, àwọn ìjọba yóò ti ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì yẹ ní àkókò.

Ní agbára Olódùmarè, tí àwọn ajẹgàba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà bá ti fi ìtìjù kúrò lórí ilẹ̀ wa ní àìpẹ́ yí, tí àwọn adelé wa bá ti wà ni ipò wọn, ọkàn àwọn akékòó yóò balẹ̀, nítorí màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla jẹ́ kí a mọ̀ pé kò gbọdọ̀ sí ọmọ tí kì yóò ní àǹfààní sí ẹ̀kọ́, nítorí ẹ̀kọ́ ọfẹ ni ètò ẹ̀kọ́ máa jẹ́ ní orílẹ̀ èdè DRY.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024

Àwọn olùkọ́ kì yóò yan iṣé lódì mọ, wọn á máa rí owó ọ̀yà àti ẹ̀tọ́ wọn gbà déédé, pẹ̀lù ẹ̀tọ́ si gbogbo ohun amáyé dẹrùn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́. 

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pàápàá kò ní ló ju iye ọdún tàbí àsìkò tó yẹ ki wọ́n lò. Ṣé aò gbàgbé wípé nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí olórí ìjọba adelé orílẹ̀ èdè DRY bá wa sọ níbi tí wọ́n ti mẹ́nuba ètò ẹ̀kọ́ wípé kí gbogbo ilé ìwé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá DRYwà ní títì pa, èyí ni láti leè ṣe àtúpalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ kí ó sì leè rọrùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́,ṣùgbọ́n jíjẹ gàba àwọn ìjọba ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ló fa bi ètò ẹ̀kọ́ DRY se rí títí di ìsinsìnyí.

Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, inú dídùn ní mú orí yá, iṣẹ́ yóò wà fún àwọn ọ̀dọ́, yálà láti ṣiṣé gbowó tàbí láti dá iṣẹ́ ara ẹni sílẹ̀. Ìfọkànbalẹ̀ yóò wà fún ọjọ ọla rere lẹ́yìn ẹ̀kọ́ wọn gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla, ìyá wa ìrọ̀rùn ló bá dé.