Ọba Charles ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti bu ọwọ́ lu àwọn òfin tuntun ní ìlú rẹ̀, tí àwọn òfin wọ̀nyí sì sọ pé kò di dandan kí á kọ̀ọ́ sí ara àwọn ayédèrú oúnjẹ (GMO) pé ayédèrú ni wọ́n! Èyí túmọ̀ sí pé ẹni tó ń ra’jà kò le mọ̀ bí oúnjẹ àbáláyé (organic) ni wọ́n ń tà fún òun, tàbí ayédèrú (GMO).
Pẹ̀lú gbogbo ìjàǹbá tí a ti mọ̀ báyi, tí oúnjẹ àti irúgbìn GMO máa ń fà, èyí já sí pé ẹni tí ó bá ń ra ohunkóhun tí ẹnu ń jẹ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kò le mọ̀ bóyá ìpalára ni òun ń fi ọwọ́ ara òun rà, tàbí oúnjẹ ànfààní! Ọ̀nà tí àwọn amúnisìn wọ̀nyí ń gbà láti tún ṣe iṣẹ́ ibi wọn nìyí!
Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ mọ̀ pé Ọba Charles fún’ra rẹ̀ kìí jẹ ohunkóhun tí ó jẹ́ GMO !? Irú ìwà ìkà tí àwọn “alágbayé” (globalists) wọ̀nyí ń ṣe nìyẹn !
Fọ́nrán kan ló fi èyí hàn wá lórí ẹ̀rọ ayélujára ní’bi tí ọkùnrin òyìnbó kan bíi ti Charles fún’ra rẹ̀ ti sòrò lórí oúnjẹ àyípadà àti tí ÀBÁLÁYÉ, tí ó sì tọ́ka sí àgàbàgebè Ọba Charles yi.
Ó ní kò sí ibi tí Charles ń lọ ní àgbáyé yí tí àwọn olóńjẹ tirẹ̀ kìí tẹ̀lée, tí wọ́n á sì gbé oúnjẹ rẹ̀ dání. Kò s’ohun tó búrú nínú ìyẹn, ṣebí bó ṣe wu’ni l’a ṣe ń ṣe nǹkan ẹni; ṣùgbọ́n ohun tó burú níbẹ̀ ni pé, àwọn olónjẹ Charles kò gbọdọ̀ fi oúnjẹ GMO kankan sáarín oúnjẹ Charles ọ̀ún, tórí ó mọ ewu ń lá tó wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n òun kannáà yí ló sọ pé wọ́n lè ta oúnjẹ GMO ní ìlú òun láì sọ fún oníbarà pé GMO ni o!
Àwa ọmọ-ìbílẹ̀-Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ó ti wá hàn gbangba báyi, pé àwọn “alágbayé” (globalists) amúnisìn wọ̀nyí, kò ní’fẹ́ ẹnikan-kan, ìkórira tí wọ́n ní fún aláwọ̀dúdú kò ṣe é fẹ’nu sọ, kódà wọ́n kórira ara wọn pàápàá.
Gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe wọ̀nyí, wọ́n ti tò ó sílẹ̀, kì í ṣe òní ! Ní ọjọ́ kéjìlélógún oṣù ṣẹrẹ okòó-lé-lẹ́gbàá ọdún, ni Ọba Charles yí ti sọ́, pé, “Àkókò tí a níláti gbé ìgbésẹ̀ nìyí.” Ìgbésẹ̀ kíni o?
Ìgbésẹ̀ láti kó gbogbo ayé papọ̀ sábẹ́ òrùlé kan! Kí wọ́n lè máa jẹgàba lórí àgbáyé, láìṣe Olódùmarè. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), kò sí lára àwọn tí wọ́n máa jẹgàba lé lórí.