Èyí ni bí àwon olùgbé ṣe lè dáàbò bo ara wọn:

Ó hàn gbangba pé ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn kan tí orúko rè ńjẹ́ SÀHÁRÀ gbée jáde wípé àrùn kan tí wọ́n ńpè ní ‘Onígbáméjí ṣẹ́ yọ ní Ìlú Èkó, nítorínáà àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ẹ Yorùbá níláti tètè kíyèsára.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Àjàkálẹ̀-Àrùn Ún Ṣẹ́ Yọ N'ílùú Ìpínlẹ̀ Èkó, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Yorùbá

Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorípé ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá Olómìnira Tòṣèlúaráìlú DRY kò tíì Bẹ̀rẹ̀ ní sànánsànán nítorípé àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí ti Ìlúu Nàìjíríà ṣì takú s’órí ìjókòó ibití ó yẹ kí àwọn ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá Olómìnira Tòṣèlúaráìlú DRY tiwa jókòó sí láti máa ṣe ìjọba wọn, èyí tí ó sì lòdì sí òfin àgbáyé.

Ka Ìròyìn: Ẹrù ìjọ̀gbọ̀n ni ó nwọ’lé sí Ìlẹ̀ Yorùbá yío, Ẹ ṣọ́’ra

Èyí ló fàá tí irú àrùn báyìí fi ṣẹ́yọ lórí ilẹ̀ẹ wa, nítorí bí ó bá jẹ́ pé ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá tí bẹ̀rẹ̀ ní sànánsànán ni, ìpèsè tí wà fún omi ẹ̀rọ t’ó mọ́ gaara, ináa mànàmáná t’ó dúró wáḿ àti oríṣiríṣi àwọn ohun amáyédẹrùn báwọ̀nọnnì ní ìjọba wá ti pèsè sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọn kò tíì lè dáwọ́lé níwòn ìgbà tí àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí wọ̀nyí bá ṣì wà lórí àga tí ó yẹ fún ìjọba wá èyí tí ó lòdì sí òfin àgbáyé.

 

Àjàkálẹ̀-Àrùn Ún Ṣẹ́ Yọ N'ílùú Ìpínlẹ̀ Èkó, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Yorùbá