Ìròhìn nípa bí agbára ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ọlọ́pọlọ pípé orílẹ̀ èdè Amẹrika ṣe n dínkù síi ní agbègbè ìwọ̀ oòrùn Afrika latàrí bí wọ́n ṣe kúrò ní orílẹ̀ èdè Niger.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ìwé ìròyìn ayélujára kan tí a npè ní Reuter gbé ìròyìn kan jáde ní ọjọ́ karundínlọgbọ̀n oṣù òkúdù, ẹgbàá ọdún ó lé mẹrinlélogún ti sanmoni òde òní latari bí ẹgbẹ́gun orílẹ̀ èdè Amẹrika ṣe di igbá di agbọ̀n àwọn irinṣẹ́ àti ẹka tí ó nkojú àwọn agbésùnmọ̀mí kúrò ní orílẹ̀ èdè Niger. 

Gẹ́gẹ́bí ó ṣe sọ, ó túbọ̀ n ṣòro si láti ṣàmojútó ọsẹ́ tí àwọn koloransi agbésùnmọ̀mí ẹ̀dá wọ̀nyí nṣe ni ìwọ̀-oòrùn Afrika.

Tí a kò bá gbàgbé, ìjọba ológun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìjọba ní Niger ti fún ẹgbẹ́gun orílẹ̀ èdè Amẹrika ní gbèndéke ọjọ́ kẹẹdogún oṣù owewe ọdún ti a n báa lọ yí lati palẹ̀ ẹrù wọn mọ́ ní Niger.

Òmìnira Yorùbá daily news updates

 

Ọ̀gágun àgbà olórí àwọn ọmọ ogun orí omi orílẹ̀ èdè Amẹrika tí a mọ̀ sí Michael Langley tí ó n darí ẹgbẹ́gun Amerika ni Afrika sọ wípé ìpèníjà tí àwọn ẹgbẹ́gun rẹ̀ dojú kọ báyii ni láti mọ ìpete pèrò àti ìgbésẹ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí Al-Queda àti IS, pàápàá tí ó lòdì sí orílẹ̀ èdè wọn ati Europe. Èyí túmọ̀ sí wípé góngó ìlépa wọn ni ààbò ìlú wọn. 

Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ṣe àkíyèsí wípé láti ìsinyí lọ á sòro fún orílẹ̀-èdè Amerika lati ṣe àwárí ipa ẹsẹ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí wọ̀nyí èyítí ó gba àmójútó àrà ọ̀tọ̀. 

Wọ́n ṣe é lalàyé wípé bẹ̀rẹ̀ lati ọdún 2020 ni àwọn ológun ni orílẹ̀ èdè Mali, Burkina Faso àti Niger ti n gbajọba tí wọn sì ti kọ ẹhìn sí àwon ìbáṣepọ̀ oludá àbò bò ti America, Faransé ati Ìparapọ̀ àwon orílẹ̀-èdè. Nipò wọn, wọ́n kọjú sí orílẹ̀-èdè Russia fún ìrànlọwọ́.

Èyí tí ó kàn wá, gẹ́gẹ́bí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ni kí á ri wípé ìlú kankan tàbí orílẹ̀-èdè kankan kò sọ ilẹ̀ Yorùbá di ibi tí wọ́n máa máa di ẹrù ìjà-ogún wọn sí ní orúkọ “ìbáṣepọ̀ ìdáàbòbò,” àti wípé a kò tilẹ̀ gbọ́dọ̀ fi àyè gba agbésùnmọ̀mí kankan ní orílẹ̀-èdè Yorùbá.

Òmìnira Yorùbá daily news updates