ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI
OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.
ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
Akọ̀ròyìn kan ló sọ fún wèrè tó fi ipá dúró sí oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) wa, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, èyíinì, èyí tó pera rẹ̀ ní Adémọ́lá Adélékè pé, ìgbàyí làárọ̀?
Kò sí ẹni tí ó lè yipadà, Orílẹ̀-Èdè D.R.Y ti kúrò lára Nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, bẹ́ẹ̀ ni a sì ti gba agbára ìṣèjọba-ara-ẹni wa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù Igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún; nítorí èyí, ohunkóhun tí ó wù kí Adémọ́lá Adélékè máa dáwọlé ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní D.R.Y, ó ń dá ọ̀ràn kún ọ̀ràn ni.
Àgbáyé ti mọ̀ pé D.R.Y kìí ṣe ara Nàìjíríà mọ́ nítorí náà, ìwọ Adélékè, o ń ṣe àṣedànù ni! O sì máa jẹ́’jọ́ láìpẹ́, lórí jíjẹgàba tí o jẹ gàba lórí ilẹ̀ D.R.Y ní ìlú Òṣogbo. Tètè máa lọ; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, o máa kan ìdin nínú iyọ̀.
Gẹ́gẹ́bí ìròyìn tí a gbọ́ náà ṣe sọ, Adèlékè ọmọ-àlè tó pe’ra rẹ̀ ní Yorùbá yí, ń pín oríṣiríṣi ohun èlò fún iṣẹ́ ọ̀gbìn ní agbègbè Ẹdẹ, orílẹ̀-èdè D.R.Y, l’ẹyìn oṣù mẹ́rin-àbọ̀ tí ìjọba D.R.Y ti wà lórí ipò. Adélékè, ẹ̀wọ̀n ẹ á ju ti ọ̀bọ lọ!
Tí ó bá tún jẹ́ irúgbìn GMO ni o kó lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè D.R.Y, ìwọ Adélékè, mọ̀ dájú pé ẹ̀sùn ìpànìyàn ni o máa jẹ́ ẹjọ́ rẹ̀!
Gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ìgbà díẹ̀ ló kù ó, Olódùmarè ti fún wa ní ìṣẹ́gun; ẹ máṣe tẹ̀lé olóṣèlú Nàìjíría; Yorùbá kò sí lára Nàìjìríà mọ́!
Àlàkalẹ̀ fún ìṣerere ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá, èyí tí Olódùmarè tí ipa Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, gbe fún wa, ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ ètò fún iṣẹ́ àgbẹ̀, láti ìgbà tí ìjọba-Adelé wa bá ti bọ́ sí àwọn oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, DRY).
Olórí Ìjọba-Adelé wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ mọ pàtàkì iṣẹ́ ọ̀gbìn; wọ́n sì ti ní gbogbo bí ó ṣe máa dára lọ́kàn, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ tọ̀ọ́, nítorí ohun àmúyangàn ni iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè D.R.Y.
Ẹ jẹ́ kí a rántí o, ẹ̀sùn ìpànìyàn ló jẹ́, ní orílẹ̀-èdè Yorùbá (D.R.Y) láti gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, tàbí láti fún ẹnikẹ́ni ní irúgbìn GMO.