Ẹ̀rọ ayélujára X, ló gbé fọ́nrán ọkùnrin àgbé’nipá’wó kan jáde níbi tí wọ́n ti ń fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, tí ó sì wá ń tọrọ àforíjì báyìí wípé kí wọ́n sáànú òun, ó ní òun kábáámọ̀ ìgbésẹ̀ náà,àti pé ìgbà àkọ́kọ́ ni eléyìí.

Ọ̀ jálé onílé fi bo tirẹ̀ lẹ́yìn, ó wípé, owó tí àwọn ẹlẹgbẹ́ òun pín kan òun, ṣe ni òun fi san owó ilé-iwé àwọn ọmọ , ó sì fi èyí tí ó kù jẹun. Njẹ́ tí ó bá ṣe pé ọmọ tìrẹ ní wọn gbé pa’wó, báwo ni ìbá ṣe rí lára rẹ̀?

Ẹ̀yin ase’kúpani, tí kìí fẹ́ kí wọ́n mú idà kọjá lórí yín, ẹ lọ ronú pìwàdà. Ẹyin olórí orílẹ̀-èdè ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ẹyin ni ẹ ń fà gbogbo ìwà burúkú tí ó gbilẹ̀ yí. Èyí tí ọ̀rọ̀ yí fi kàn wá ni pé, àkọlé kan lórí fọ́nrá náà sọ pé ìlú Èkó, tó jẹ́ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni ọ̀daràn náà wà, torí àwa kìí ṣe Nàìjíríà; ìjẹgàba wọn lórí ilẹ̀ wa ló fa ìríkúri wọ̀nyí.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń hù ìwà burúkú káàkiri yìí, ẹyin ní ẹ ò fún wọn ní’sẹ́, nígbà tí àwa ṣì wà nínú Nàìjíríà; tí ẹ ò dẹ̀ tún dá wọn ní oko òwò. A kúrò nínú Nàìjíríà yín tán, ẹ tún nfi ipá dúró lórí ilẹ̀ wa!

Àwa ọ̀dọ́ Indigenous Yorùbá People (I.Y.P.), tí a wà lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y.), a kú oríire o, nítorí pé, Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modupeọlá Onitiri-Abiola, tí torí tiwa fi orí la ibú já, kí á ba le rí ògo wa lò ní Orílè-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y); kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹlẹ́dàá wa ti ó pe ìránṣẹ́ Rẹ̀, ìyá Abiyamọ tòótọ́, MOA, láti wá gbà wá kúrò nínú iṣẹ́ tí a bá ara wa.