Àṣírí Àwọn Ọba Apànìyàn Àti Òdómodé Alápatà Ti Tú O 

 

Ẹ̀yin I.Y.P (Indigenous Yorùbá People), ẹ jẹ́ kí a máa mọ irú ọ̀rẹ́ tí a máa bá rìn o. Ìdí ni pé ìròyìn tí a gbọ́ lórí ẹ̀rọ móhùn máwòrán TVC, ní ọjọ́ karùn-ún oṣù keje Ẹgbàá odún ó-lé mẹrin-lé-lógún, jẹ́ kàyéfì. Ọ̀rẹ́ tán ọ̀rẹ́ ẹ̀ lọ pa, láti ta ẹ̀yà ara ẹ̀ fún owó pọ́ọ̀kú.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Adémọ́lá, tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ní itẹ́ òkú kan, ni a gbọ́ pé ó sọ ara ẹ̀ di alápatà ẹ̀yà ara ènìyàn, fún owó tásọ́rẹ́, nítorí pé àwọn tí ó ń bèrè fún ẹ̀yà ara ti pọ̀ si. Ó ń ta orí ènìyàn ni àádọ́ta ẹgbẹ̀rún náírà, ọwọ́ tàbí ọkàn ni ẹgbẹ̀rún márun-dínlọgbọ̀n, sí ọgbọ̀n ẹgbẹ̀rún náírà.

 

Gbogbo àwa I.Y.P, ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra fún ọrẹ o.

È wo ni tí odidi ọba ìlú, tí wọ́n ń pè ní kábíyèsí, tí ó ní kí Ademola bá òun pa ọmọ bíbí inú òun, ki wọ́n kun-ún, nítorí òun nílò ẹ̀yà ara ẹ̀. Ṣé ẹ wá ri wípé kàyéfì ńlá ní eléyìí. Ẹ ò bẹ̀rù Olódùmarè, ẹyin ọba ìkà, ọ̀dájú abiyamọ wọ̀nyí. Báwo ni ẹ̀mí ará ìlú tí ó wà ní agbègbè yín ṣe máa nítumọ̀ sí yín? Olódùmarè tí rí ọkàn àti ìwà ọwọ́ yín, pé ó kún fún ẹ̀jẹ̀, ni Ó ṣe fa ìjọba yín ya ní orí ilẹ̀ D.R.Y (Democratic Republic of the Yoruba). Àwa kò fẹ yín ní ọba mọ́ o. Olódùmarè ti kọ̀ yín sílẹ̀.

Àṣírí Àwọn Ọba Apànìyàn Àti Òdómodé Alápatà Ti Tú O 

Ká Ìròyìn Síwájú sí: