Ìkíni jẹ́ ohun tí a máa ń sọ tàbí ṣe láti ṣe àpọ́nlé ènìyàn. Yorùbá ní oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n fi ń kíni ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, lórí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò kan tàbí lórí ohun tí ènìyàn ńṣe lọ́wọ́lọ́wọ́,àti fún oríṣiríṣi ayẹyẹ.

Ìkíni jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì tí àwọn Yorùbá ń gbà bọ̀wọ̀ fún ara wọn àti láti fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn pẹ̀lú ẹ̀rín àti ọ̀yàyà. Láti kékeré ni ìran Yorùbá ti máa ńkọ́ àwọn ọmọ wọn bí wọ́n ṣe ń kí ènìyàn, ọmọ tí wọ́n bí, tí wọ́n kọ́ tí ó sì gbà, lára ìkíni ni ẹ ó ti kọ́kọ́ mọ.

Ní ilẹ̀ Yorùbá, ọmọkùnrin máa ń dọ̀bálẹ̀ láti kí ènìyàn ni, nígbà tí ọmọbìnrin sì máa ń wà ní ìkúnlẹ̀.

Báyìí ni àwọn Yorùbá ṣe máa ń kíni ní àwọn àkókò wọ̀nyí:

Àárọ̀- Ẹ ká àárọ̀,Ìyálẹ̀ta- Ẹ kú ìyálẹ̀ta, ọ̀sán - Ẹ káàsán, Ìrọ̀lẹ́-Ẹ kú ìrọ̀lẹ́, Alẹ́- Ẹ káalẹ́, Àkókò òjò - Ẹ kú òjò, àkókò ọ̀gìnnìtìn- A kú ọ̀gìnnìtìn, àkókò ooru—A kú ooru àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Báyìí ni àwọn Yorùbá tún ṣe máa ń kí àwọn onísẹ́ wọ̀nyí: Àgbẹ̀- À roko bọ́dún dé o, Ọlọ́dẹ- À rèpa ògún, Aláró- À rẹdú o, Awakọ̀- Ọkọ̀ árèfó, Akọ̀pẹ- Igbà á rọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìran Yorùbá tilẹ̀ tún máa ń kí ẹni tí wọ́n bá ti rí fún ìgbà díẹ̀ báyìí wípé, ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta ó, Ẹnití ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìrìn àjò Ẹ kú ìrìn, ṣé dáadáa ni ẹ dé, tí a sì tún máa ń kí àwọn ẹni tí ó gba àlejò báyìí wípé, ẹ kú àfojúbà. Yorùbá fẹ́ràn ìkíni púpọ̀ débi wípé, wọ́n á tún máa kí ara wọn lórí oúnjẹ.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ṣùgbọ́n ó ṣe ni láàánú wípé, púpọ̀ nínú àwọn àṣà Yorùbá wọ̀nyí ni a ti fi ọwọ́ rọ́ sí apákan tí a sì ti gbé àṣà tí àwọn amúnisìn tí kò fi ibì kankan dára tó tiwa débi wípé yóò dára ju tiwa lọ, ṣùgbọ́n kí á dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó gbà wá nípasẹ̀ ìránṣẹ́ tí ó rán síwa, màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gbà wá àti láti dá gbogbo àwọn àṣà wa tí wọ́n ti di ohun ìgbàgbé padà, màmá sì ti fi ìgbà kan sọ fún wa wípé, a ó padà sí bí àwọn babańlá ti ń ṣe láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ní.

Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a máa gbára dì, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àtúnṣe ní gbogbo ọ̀nà tí a bá ti gbà sọ àṣà wa nù, kí a sì mọ̀ wípé kò sí àṣà náà níbikíbi tí ó dára tó àṣà àwa ìran Yorùbá.