Proverb: A ta bàbà, a fowó-o bàbà ra baba
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó rán màmá wá MOA, Modupeola Onitiri-Abiola, sì àwa ọmọ Aládé, tí wọ́n wá kó wa padà wá sórí ilẹ̀ àjogúnbá àwọn bàbà ńlá wa.
Ní báyìí, ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ sí máa gbé àṣà wá lárugẹ o.
Ẹyin IYP obinrin ni mo fẹ́ rán létí bí a ti le fi ọsẹ àbùwẹ̀, osùn àti àdíàgbọn ṣe àtúnṣe ara wa bíi àwọn ìyá wa ni àtijọ́, tí àwọ wá, tí òòrùn tàbí àwọn òróró ìkun’ra oríṣiríṣi tí a ti ń lò ṣùgbọ́n tí ó ti bà wà ní àwọ̀ jẹ́, tàbí bóyá ẹni tí ó fẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jí pé pé ni, ó ní bí a ṣe máa lò wọ́n.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Ọsẹ àbùwẹ̀ jẹ́ ọsẹ ìbílẹ̀ wá tí ó máa ń hó dára dára tí ó sì máa ń fọ ara mọ ṣáká, tàbí, tí ẹ kò bá fẹ́ ọsẹ àbùwẹ̀ tiwa, ẹ le lo ọsẹ tí ó bá wù yín.
Bákanná, ni osùn ṣe jẹ́ ohun tí àwọn ìyá wa máà ń fi pa ara lẹ́yìn tí wọ́n bá wẹ́ tán, a lé ríi rà ní ọ̀dọ̀ àwọn eléwé ọmọ, ṣùgbọ́n, dípò kí a fi pa ara bíi òróró ìpara bíi ti àwọn ìyá wa, a máa fi wẹ́ ni o.
Bí a ṣe máa lò ó ní pé, ẹ máa ju ẹyọ méjì osùn sínú omi tí ẹ bá ti fẹ́ wẹ́ fún bíi ìṣẹ́jú díẹ̀ kí ó le rọ̀, tí ẹ bá ti fi ọsẹ sí orí kàìnkàìn tán, ẹ mú osùn kan kí ẹ fi ọwọ́ lọ̀ọ̀ mọ́ ọsẹ, kí ẹ má a fi wẹ́, tí ìyẹn bá ti yòrò tán, ẹ fi íkejì sii, lẹ́yìn ìwẹ̀, kí ẹ má fi táwẹ́lì nu’ra, kí ẹ wá rọra fi àdíàgbọn pa omi yẹn mọ̀ ara, torí, àdíàgbọn máa ń tún àwọ ṣe ni, hhhmmm!, kò s’arúgbó ni’lẹ̀ D.R.Y. ní o, nítorí, tí ẹ bá ń lò ó déédéé, ó máa rẹ irun ara yín sílẹ̀ ni, tí ara tún máa jí pé pé tí á máa dán, nítorí, osùn máa ń pa kòkòrò ara ni, ẹwà yín máa wá dà bíi ti àwọn sisí wa.
Ní pàtàkì jùlọ, kí á máa fi wẹ́ ọmọ tuntun tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, láti ìgbà tí a bá tí gbé wọn dé’lé láti ilé ìgbẹ̀bí, háà!, ẹwà ní o
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÀMERICA TI F’ỌWỌ́ SÍ ỌSIN ADÌẸ LÁTI YÀRÁ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀
- ẸGBẸ̀RÚN MÁRUN NÁÍRÀ NI ÀWỌN ARÁ ÌLÚ NÀÌJÍRÍÀ FI DA’LẸ̀ ARA WỌN !
- ÀNFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
- ÒFÉGÈ ÌRÀNLỌ́WỌ́: ọmọ Yorùbá, máṣe yà sí’bẹ̀ !
- ỌMỌKÙNRIN KAN ṢE’KÚ PA BÀBÁ TÓ BÍ BÀBÁ RẸ̀ NÍTORÍ OKO
- JAMIU ABÍỌ́LÁ NHU ÌWÀ ỌMỌ ALÈ