Yoruba Nation the newest Nation in the world.

Fún èyin tí ẹ maa nsọ pé èròngbà rikiṣi lásán ni pé àwọn Àjọ Alákoòso Ẹ́yáwó ní Àgbáyé (IMF), Banki Àgbáyé àti Àjọ Aṣewadi Abẹ́lẹ̀ ní Amẹrika (CIA) n fi ìkóniláyàjẹ àti iṣẹ̀rùbani  mú àwọn ààrẹ, olórí orilẹ-ède àti gbogbo àwọn aṣiwaju afrika láti tìwọ́n ṣe ohun ti o lòdì sí ọmọ orile-ede Afrika, ẹ fèsì sí ìbéèrè yìí:

Kíni Obasanjọ nsọ nípa rẹ̀ nínú fọ́nrán amóhùnmáwòrán yìí nigbati ó sọ ọ̀rọ̀ ti o jáde lẹ́nu rẹ yi, ki ní ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ yí pé “ìwọ kò gbọdọ̀ kọ̀ fún àwọn IMF, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wọn ó fi imú rẹ gbolẹ̀”? Kíni ìtumọ ọ̀rọ̀ yẹn? Ó sí tún wípé “ma ṣe ìfẹ́ wọn” kíni ìtumọ eyi?.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Tí àwọn ọmọ Nigeria bá farabalẹ̀ ṣe àgbéyẹ̀wò àti àtúpalẹ̀ gbogbo àkókò tí Obasanjọ jẹ olórí ní Nigeria, wọn á ri pé òun ni yíò fẹ́ẹ̀ jẹ́ ààrẹ wọn ti o burú jùlọ, kì íṣe pé torí pé ó jẹ̀ ènìyàn burúkú ṣùgbọ́n nítorí ọwọ́ ipá àwọn IMF àti Bánkì àgbáyé lórí rẹ̀ ni.

Ní ẹgbẹ̀wáọdúnódínméjìlélógún àwọn àjọ ayáni l’ówó agbaye yí fi ojú rẹ̀ rí wàhálà púpọ.

Nígbàtí ó wá fojúsí yakubu Gowon gẹ́gẹ́bí ẹnití ó fa ikú Murtala Muhammed tí ó jẹ́ ọ̀gá òun tẹ́lẹ̀, ó bèèrè lọwọ ọba-bìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fún dídápadà Gowon sí Nigeria láti jẹ́jọ́ ẹ̀sùn náà, bóyá láti ràn lọ sí ẹ̀wọ̀n tàbí kí wọ́n fi ìbọn pá, ṣùgbọ́n ìlú náà kọ̀ jálẹ̀, èyí sì fa àìgbọ́raẹniyé laarin Nigeria àti ilẹ Gẹ̀ẹ́sì.

Nitori èyí, kàkà kí ó dá Nigeria padà sí ètò ìṣèjọba awọn aṣojú (parliamentary system) tí àwọn ológun dàrú ní ẹgbẹ̀wáọdúnódínmẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, Obasanjọ pinnu láti ta Nigeria fún Amerika nitori àwọn IMF, Banki Àgbáyé àti CIA, ó gbà ètò ìṣèjọba ti ààrẹ pẹlu gbogbo ìwà àjẹbánu ìkówoójẹ tí wọn ńrí  di òní yi bẹ̀rẹ̀.

Ó wá farahàn gbangba bayi pé awọn IMF ati Bánkì Àgbáyé kò fi àyè sílẹ̀ fún àwọn olórí orílẹ̀-èdè àti ààrẹ Afrika láti ṣe ìlú bí wọ́n ti fẹ́ ṣe é, àwọn ọmọ Nigeria gbọ́dọ̀ gba ara wọn kúrò nínú èyí.

Obasanjọ mọ̀ dájú nípa lẹ́tà ìjọba Amerika tí ó kọ lati ọwọ́ ikọ̀ rẹ̀ sí Nigeria tí ikọ̀ rẹ̀ sì fún Murtala Muhammed ninu Dodan barracks. Lẹta náà jẹ́ láti fi ọgbọ́n dẹ́rùba olórí Nigeria nígbànáà, Murtala Muhammed pé kí ó má gbè lẹ́hìn orílẹ̀-èdè Congo (Angola).

say no to gmo foods, seed, crop. yoruba warns african

Wàhálà kan bẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀, awọn Amẹrika sì fẹ́ kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ gbà ìjọba lọ́wọ́ ojúlówó olórí ìlú nítorítí ó ńgbè sẹ̀hin Russia tí ó jẹ́ USSR nigba nà, awọn Amerika ǹfi owó gbè léhìn awọn ọlọ̀tẹ̀ ṣugbọn South Africa àti Ẹgbẹ́ ìṣọ̀kan Afrika (OAU) gbè lẹ́hìn ìjọba gangan tí o faramọ́ Russia, Amerika ńti South Africa, ó wá ńhalẹ̀ mọ́ Murtala ati OAU lati kẹ̀hín sí ìjọba gangan.ẹ́yi wá mú kí Murtala Muhammed binu gan.

Murtala ti ṣètò tẹ́lẹ̀ pé kí igbákejì òun Obasanjọ lọ ṣe ojú oun ní ìpàdé OAU náà níbití wọ́n ó ti parapọọ̀ lati gbè lẹ́hìn ìjọba Coògo (Angola), ṣugbọn ìbínú lẹ́tà ìhalẹ̀mọ́ni yi ló mú kí Murtala pinnu láti lọ fúnra rẹ̀. lẹ́tà náà wà lórí ẹ̀rọ ayélujára. ohun tí Murtala ṣe tí ó dun Amerika ati àwọn tí wọ́n jọ ńparapọ̀ ṣèbàjẹ́ ni pé o tẹ lẹta náà jáde nínú ìwé ìròhìn New York Times ní Amerika tí gbogbo ênìyàn ríi kà, Obasanjọ sì mọ̀ dájú pé ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lẹ́hìn náà ni wọ́n pa Murtala Muhammed ati pé ọ̀kan lára ìdí tí Dimka ní òun fi paá ni pé Murtala ńfaramọ̀ USSR. Ẹ fi òye to ọ́rọ̀ náà pọ̀, ṣé ẹ fẹ́ wipe CIA, IMF ati Bánkì Àgbáyé kò lọ́wọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà?

Pẹlu bí Obasanjọ ṣe mọ̀ ipa búburú Amerika yìí, kàkà kí ó kẹ́hìn sí wọn ṣe ní ó pinnu lati ta Nigeria fún wọn. Nigbati Obasanjọ padà wá ni egbẹ̀wáọdúndínọ̀kan, ó farahàn pé àwọn gbèdéke IMF ati Bánkì Àgbáyé tún tíì ní ìtìkutì…

Èyí ńfihàn wá pé nigbati íjọba adelé wa ni DRY bá ti wọlé agbára tán, lẹ́hìn tí a bá ti lé Nigeria ajégàba dànù lórí ilẹ̀ wá, a gbọ̀dọ̀ sá fún oko ẹrú gbèsè bí Màmá wa MOA àti àwọn Adelé wa ti ṣèlérí, nitori awọn aláwọ̀ funfun yí kò fẹ́ ire fún orílẹ̀ èdẹ̀ Afrika. IYP kò ní lọ sí oko ẹrú kejì bóyá nílé tàbí ní òkè òkun.

Ìtẹ́lọ́rùn àti ìṣọ́ra ni yíò ma tọ́ ìṣísẹ̀ wa nínú Democratic Republic of the Yoruba.